Saamu 69
Fún adarí orin. Tí ohùn “Àwọn Lílì.” Ti Dafidi.
Gbà mí, Ọlọ́run,
nítorí omi ti kún dé ọrùn mi.
Mo ń rì nínú irà jíjìn,
níbi tí kò sí ibi ìfẹsẹ̀lé.
Mo ti wá sínú omi jíjìn;
ìkún omi bò mí mọ́lẹ̀.
Agara dá mi, mo ń pè fún ìrànlọ́wọ́;
ọ̀fun mí gbẹ, ojú mi ṣú,
nígbà tí èmi dúró de Ọlọ́run mi.
Sm 35.19; Jh 15.25.Àwọn tí ó kórìíra mi láìnídìí
wọ́n ju irun orí mi lọ,
púpọ̀ ni àwọn ọ̀tá mi láìnídìí,
àwọn tí ń wá láti pa mí run.
A fi ipá mú mi
láti san ohun tí èmi kò jí.
 
Ìwọ mọ òmùgọ̀ mi, Ọlọ́run;
ẹ̀bi mi kò pamọ́ lójú rẹ.
 
Má ṣe dójútì àwọn tí ó ní ìrètí nínú rẹ nítorí mi,
Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun;
má ṣe jẹ́ kí àwọn tó ń wá ọ dààmú nítorí mi,
Ọlọ́run Israẹli.
Nítorí rẹ ni mo ń ru ẹ̀gàn,
ìtìjú sì bo ojú mi.
Mo jẹ́ àjèjì si àwọn arákùnrin mi;
àlejò sí àwọn arákùnrin ìyá mi;
Jh 2.17; Ro 15.3.nítorí ìtara ilé rẹ jẹ mí run,
àti ẹ̀gàn àwọn tí ń gàn ọ́ ṣubú lù mí.
10 Nígbà tí mo sọkún
tí mo sì ń fi àwẹ̀ jẹ ara mi ní ìyà
èyí náà sì dín ẹ̀gàn mi kù;
11 nígbà tí mo wọ aṣọ àkísà,
àwọn ènìyàn ń pa òwe mọ́ mi.
12 Àwọn tí ó jókòó ní ẹnu ibodè ń bú mi,
mo sì di orin àwọn ọ̀mùtí.
 
13 Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi ni
ìwọ ni èmi ń gbàdúrà mi sí Olúwa,
ní ìgbà ìtẹ́wọ́gbà
Ọlọ́run, nínú ìfẹ́ títóbi rẹ,
dá mi lóhùn pẹ̀lú ìgbàlà rẹ tí ó dájú.
14 Gbà mí kúrò nínú ẹrẹ̀,
má ṣe jẹ́ kí n rì;
gbà mí lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra mi,
kúrò nínú ibú omi.
15 Má ṣe jẹ́ kí ìkún omi bò mí mọ́lẹ̀
bẹ́ẹ̀ ni má ṣe jẹ́ kí ọ̀gbìn gbé mi mì
kí o má sì ṣe jẹ́ kí ihò pa ẹnu rẹ̀ dé mọ́ mi.
 
16 Dá mí lóhùn, Olúwa, nínú ìṣeun ìfẹ́ rẹ;
nínú ọ̀pọ̀ àánú rẹ yípadà sí mi.
17 Má ṣe pa ojú rẹ mọ́ fún ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ:
yára dá mi lóhùn, nítorí mo wà nínú ìpọ́njú.
18 Súnmọ́ tòsí kí o sì gbà mí là;
rà mí padà nítorí àwọn ọ̀tá mi.
 
19 Ìwọ ti mọ ẹ̀gàn mi, ìtìjú mi àti àìlọ́lá;
gbogbo àwọn ọ̀tá mi wà níwájú rẹ.
20 Ẹ̀gàn ba ọkàn mi jẹ́,
wọ́n fi mí sílẹ̀ láìsí ìrànlọ́wọ́;
mo ń wá aláàánú, ṣùgbọ́n kò sí,
mo ń wá olùtùnú, ṣùgbọ́n n kò rí ẹnìkankan.
21 Wọ́n fi òróró fún mi pẹ̀lú ohun jíjẹ mi,
àti ní òùngbẹ mi, wọ́n fi ọtí kíkan fún mi.
 
22 Jẹ́ kí tábìlì wọn kí ó di ìkẹ́kùn
ní iwájú wọn, kí ó sì di okùn dídẹ
fún àwọn tó wà ní àlàáfíà.
23 Kí ojú wọn kì í ó ṣókùnkùn, kí wọn má ṣe ríran,
kí ẹ̀yin wọn di títẹ̀ títí láé.
24  If 16.1.Tú ìbínú rẹ jáde sí wọn;
kí ìbínú gbígbóná rẹ bò wọ́n mọ́lẹ̀.
25  Ap 1.20.Kí ibùjókòó wọn di ahoro;
kí ẹnikẹ́ni má ṣe gbé nínú wọn.
26 Nítorí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí ẹni tí ìwọ ti lù,
àti ìrora àwọn tí ó ti ṣèṣe.
27 Fi ẹ̀sùn kún ẹ̀sùn wọn;
Má ṣe jẹ́ kí wọn pín nínú ìgbàlà rẹ.
28  If 3.5; 13.8; 17.8; 20.12,15; 21.27.Jẹ́ kí a yọ wọ́n kúrò nínú ìwé ìyè
kí á má kà wọ́n pẹ̀lú àwọn olódodo.
 
29 Ṣùgbọ́n tálákà àti ẹni-ìkáàánú ni èmí,
Ọlọ́run, jẹ́ kí ìgbàlà rẹ gbé mi lékè.
 
30 Èmi yóò fi orin gbé orúkọ Ọlọ́run ga
èmi yóò fi ọpẹ́ gbé orúkọ rẹ̀ ga.
31 Eléyìí tẹ́ Olúwa lọ́rùn ju ọ̀dá màlúù lọ
ju akọ màlúù pẹ̀lú ìwo rẹ̀ àti bàtà rẹ̀.
32 Àwọn òtòṣì yóò rí, wọn yóò sì yọ̀:
ẹ̀yin yóò wá Ọlọ́run, ọkàn yín yóò sì wà láààyè!
33  Olúwa, gbọ́ ti aláìní,
kì ó sì kọ àwọn ìgbèkùn sílẹ̀.
 
34 Kí ọ̀run àti ayé yìn ín,
òkun àti àwọn tí ń gbé inú rẹ̀,
35 nítorí tí Ọlọ́run yóò gba Sioni là
yóò sì tún àwọn ìlú Juda wọ̀nyí kọ́.
Kí wọn ó lè máa gbé ibẹ̀, kí wọn ó lè máa ní ní ilẹ̀ ìní;
36 àwọn ọmọ ọmọ ọ̀dọ̀ ni yóò máa jogún rẹ̀,
àwọn tí ó fẹ́ orúkọ rẹ ni yóò máa gbé inú rẹ̀.

Saamu 69:4 Sm 35.19; Jh 15.25.

Saamu 69:9 Jh 2.17; Ro 15.3.

Saamu 69:24 If 16.1.

Saamu 69:25 Ap 1.20.

Saamu 69:28 If 3.5; 13.8; 17.8; 20.12,15; 21.27.