Àwọn ọ̀rọ̀ ọba Lemueli
31
1 Àwọn ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ ti Lemueli ọba, ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ìyá rẹ̀ kọ́ ọ,
2 “Gbọ́ ìwọ ọmọ mi, gbọ́ ìwọ ọmọ inú mi!
Gbọ́ ìwọ ọmọ ẹ̀jẹ́ mi.
3 Má ṣe lo agbára rẹ lórí obìnrin,
okun rẹ lórí àwọn tí ó pa àwọn ọba run.
4 “Kì í ṣe fún àwọn ọba, ìwọ Lemueli,
kì í ṣe fún ọba láti mu ọtí wáìnì,
kì í ṣe fún alákòóso láti máa wá ọtí líle,
5 kí wọn má ba à mu ọtí yó kí wọn sì gbàgbé ohun tí òfin wí,
kí wọn sì fi ẹ̀tọ́ àwọn tí ara ń ni dù wọ́n.
6 Fi ọtí líle fún àwọn tí ń ṣègbé
wáìnì fún àwọn tí ó wà nínú ìrora.
7 Jẹ́ kí wọn mu ọtí kí wọn sì gbàgbé òsì wọn
kí wọn má sì rántí òsì wọn mọ́.
8 “Sọ̀rọ̀ lórúkọ àwọn tí kò le sọ̀rọ̀ fúnra wọn
fún ẹ̀tọ́ àwọn ẹni tí ń parun.
9 Sọ̀rọ̀ kí o sì ṣe ìdájọ́ àìṣègbè
jà fún ẹ̀tọ́ àwọn tálákà àti aláìní.”
Ìkádìí: Aya oníwà rere
10 Ta ni ó le rí aya oníwà rere?
Ó níye lórí ju iyùn lọ.
11 Ọkọ rẹ̀ ní ìgbẹ́kẹ̀lé púpọ̀ nínú rẹ̀
kò sì ṣí ìwà rere tí kò pé lọ́wọ́ rẹ̀.
12 Ire ní ó ń ṣe fún un, kì í ṣe ibi
ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.
13 Ó sa aṣọ irun àgùntàn olówùú àti ọ̀gbọ̀
Ó sì ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìyárí.
14 Ó dàbí ọkọ̀ ojú omi tí àwọn oníṣòwò;
ó ń gbé oúnjẹ rẹ̀ wá láti ọ̀nà jíjìn.
15 Ó dìde nígbà tí òkùnkùn sì kùn;
ó ṣe oúnjẹ fún ìdílé rẹ̀
àti ìpín oúnjẹ fún àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀.
16 Ó kíyèsi oko kan, ó sì rà á;
nínú ohun tí ó ń wọlé fún un ó gbin ọgbà àjàrà rẹ̀.
17 Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ tagbára tagbára
apá rẹ̀ le koko fún iṣẹ́.
18 Ó rí i pé òwò òun pé
fìtílà rẹ̀ kì í sì í kú ní òru.
19 Ní ọwọ́ rẹ̀, ó di kẹ̀kẹ́ òwú mú
ó sì na ọwọ́ rẹ̀ di ìrànwú mú.
20 O la ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn tálákà
ó sì na ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn aláìní.
21 Nígbà tí òjò-dídì rọ̀, kò bẹ̀rù nítorí ìdílé rẹ̀
nítorí gbogbo wọn ni ó wọ aṣọ tí ó nípọn.
22 Ó ṣe aṣọ títẹ́ fún ibùsùn rẹ̀;
ẹ̀wù dáradára àti elése àlùkò ni aṣọ rẹ̀.
23 A bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀ ní ẹnu ibodè ìlú
níbi tí ó ń jókòó láàrín àwọn àgbàgbà ìlú.
24 Ó ń ṣe àwọn aṣọ dáradára ó sì ń tà wọ́n
ó sì ń kó ọjà fún àwọn oníṣòwò.
25 Agbára àti ọlá ni ó wò ọ́ láṣọ
ó le fi ọjọ́ iwájú rẹ́rìn-ín.
26 A sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n
ìkọ́ni òtítọ́ sì ń bẹ létè e rẹ̀
27 Ó ń bojútó gbogbo ètò ilé rẹ̀
kì í sì í jẹ oúnjẹ ìmẹ́lẹ́.
28 Àwọn ọmọ rẹ̀ dìde wọ́n sì pè é ní alábùkún
ọkọ rẹ̀ pẹ̀lú ń gbóríyìn fún un.
29 “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ obìnrin ní ń ṣe nǹkan ọlọ́lá
ṣùgbọ́n ìwọ ju gbogbo wọn lọ.”
30 Ojú dáradára a máa tan ni, ẹwà sì jẹ́ asán
nítorí obìnrin tí ó bẹ̀rù Olúwa yẹ kí ó gba oríyìn.
31 Sì fún un ní èrè tí ó tọ́ sí i
kí o sì jẹ́ kí iṣẹ́ rẹ̀ fún un ní ìyìn ní ẹnu ibodè ìlú.