12
 1 Ẹnikẹ́ni tí ó fẹ́ ẹ̀kọ́ fẹ́ ìmọ̀, 
ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó kórìíra ìbáwí jẹ́ aláìgbọ́n. 
 2 Ènìyàn rere gba ojúrere lọ́dọ̀ Olúwa 
ṣùgbọ́n ènìyàn ètè búburú ni yóò dá lẹ́bi. 
 3 A kò lè fi ẹsẹ̀ ènìyàn múlẹ̀ nípa ìwà búburú 
ṣùgbọ́n a kò le è fa olódodo tu. 
 4 Aya oníwà rere ni adé ọkọ rẹ̀ 
ṣùgbọ́n aya adójútini dàbí inú egungun rẹ̀ jẹrà. 
 5 Èrò àwọn olódodo tọ́, 
ṣùgbọ́n ìgbìmọ̀ ènìyàn búburú jẹ́ ẹ̀tàn. 
 6 Ọ̀rọ̀ ènìyàn búburú lúgọ de ẹ̀jẹ̀ 
ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ àwọn olódodo gbà wọ́n là. 
 7 A ṣí àwọn ènìyàn búburú ní ìdí, wọn kò sì sí mọ́; 
ṣùgbọ́n ilé olódodo dúró ṣinṣin. 
 8 A ń yín ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ọgbọ́n rẹ̀ 
ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ọlọ́pọlọ wúruwùru ni a kẹ́gàn. 
 9 Ó sàn kí a má jẹ́ ènìyàn pàtàkì kí a sì ní ìránṣẹ́ 
ju kí a díbọ́n pé a jẹ́ ẹni pàtàkì láìní oúnjẹ. 
 10 Olódodo ènìyàn ń ṣe aájò ohun tí àwọn ohun ọ̀sìn rẹ̀ nílò, 
ṣùgbọ́n ìyọ́nú àwọn ènìyàn búburú, ìkà ni. 
 11 Ẹni tí ó bá dá oko yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ, 
ṣùgbọ́n ẹni tí ń lépa òjìji lásán làsàn kò gbọ́n. 
 12 Ènìyàn búburú ń fẹ́ ìkógun àwọn ènìyàn ìkà 
ṣùgbọ́n gbòǹgbò olódodo ń gbilẹ̀. 
 13 A mú ènìyàn búburú nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ 
ṣùgbọ́n olódodo bọ́ kúrò lọ́wọ́ ìdààmú. 
 14 Láti inú èso rẹ̀, ènìyàn kún fún onírúurú ohun rere 
bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ti ń pín in lérè dájúdájú. 
 15 Ọ̀nà aláìgbọ́n dára lójú ara rẹ̀ 
ṣùgbọ́n ọlọ́gbọ́n ènìyàn a máa gba ìmọ̀ràn. 
 16 Aláìgbọ́n ènìyàn fi ìbínú un rẹ̀ hàn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, 
ṣùgbọ́n olóye ènìyàn fojú fo ìyànjẹ. 
 17 Ẹni tí ó jẹ́ ajẹ́rìí òtítọ́ jẹ́rìí ohun tí ojú rẹ̀ rí 
ṣùgbọ́n ajẹ́rìí èké máa ń parọ́. 
 18 Ọ̀rọ̀ tí a kò rò jinlẹ̀ máa ń gún ni bí ọ̀kọ̀ 
ṣùgbọ́n ahọ́n ọlọ́gbọ́n ń mú ìwòsàn wá. 
 19 Ètè tí ń ṣọ òtítọ́ yóò wà láéláé 
ṣùgbọ́n ahọ́n tí ń parọ́ kì í tọ́jọ́. 
 20 Ẹ̀tàn wà nínú ọkàn àwọn tí ń pète búburú 
ṣùgbọ́n ayọ̀ wà fún àwọn tí ń mú kí àlàáfíà gbilẹ̀. 
 21 Ibi kì í ṣubú lu olódodo rárá 
ṣùgbọ́n ènìyàn búburú gba ìpín ìyọnu tiwọn. 
 22  Olúwa kórìíra ètè tí ń parọ́ 
ṣùgbọ́n ó ní inú dídùn sí àwọn olóòtítọ́. 
 23 Ènìyàn olóye fi ìmọ̀ rẹ̀ pamọ́ sínú ara rẹ̀ 
ṣùgbọ́n ọkàn ènìyàn búburú ń gbé ìwà òmùgọ̀ jáde. 
 24 Ọwọ́ àìṣọ̀lẹ yóò jẹ ọba 
ṣùgbọ́n ọ̀lẹ ṣíṣe a máa yọrí sí ẹrú ṣíṣe. 
 25 Ìbànújẹ́ ní ọkàn ènìyàn ní dorí rẹ̀ kodò 
ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ rere a máa mú kó yọ̀. 
 26 Olódodo ènìyàn máa ń ṣọ́ra láti dọ́rẹ̀ẹ́ 
ṣùgbọ́n ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú ń mú wọn ṣìnà. 
 27 Ọ̀lẹ ènìyàn kò sun ẹran tí ó pa lóko ọdẹ 
ṣùgbọ́n ẹni tí kì í ṣe ọ̀lẹ máa ń díwọ̀n ohun ìní rẹ̀. 
 28 Ní ọ̀nà àwọn olódodo ni ìyè wà 
ní ọ̀nà náà ni àìkú wà.