8
Ọgbọ́n n fi ìpè síta 
 1   Òw 1.20,21.Ǹjẹ́ ọgbọ́n kò ha ń kígbe síta? 
Òye kò ha ń gbé ohùn rẹ sókè? 
 2 Ní ibi gíga ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà, 
ní ìkóríta, ní ó dúró; 
 3 ní ẹgbẹ́ ibodè tí ó wọ ìlú, 
ní ẹnu ibodè ni ó ń kígbe sókè: 
 4 “Sí i yín ẹ̀yin ènìyàn, ní mo ń kígbe pè; 
mo gbé ohun mi sókè sí gbogbo ènìyàn. 
 5 Ẹ̀yin aláìmọ̀kan, ẹ kọ́gbọ́n; 
ẹ̀yin aṣiwèrè, ẹ gba òye. 
 6 Ẹ gbọ́, nítorí tí èmi ó sọ̀rọ̀ ohun iyebíye; 
Èmí ṣí ètè mi láti sọ ohun tí ó tọ́, 
 7 ẹnu mi ń sọ ohun tí í ṣe òtítọ́, 
nítorí ètè mi kórìíra ibi. 
 8 Gbogbo ọ̀rọ̀ ẹnu mi ni ó tọ́, 
kò sí èyí tí ó jẹ́ ẹ̀tàn tàbí àyídáyidà níbẹ̀. 
 9 Fún olóye gbogbo rẹ̀ ni ó tọ̀nà; 
wọ́n jẹ́ aláìlẹ́gàn fún gbogbo ẹni tí ó ní ìmọ̀. 
 10 Yan ẹ̀kọ́ mi dípò fàdákà, 
ìmọ̀ dípò o wúrà àṣàyàn, 
 11 nítorí ọgbọ́n ṣe iyebíye jù iyùn lọ, 
kò sí ohun tí ọkàn rẹ̀ fẹ́ tí a sì le fiwé e. 
 12 “Èmi, ọgbọ́n ń gbé pẹ̀lú òye; 
mo ní ìmọ̀ àti ọgbọ́n-inú. 
 13 Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìkórìíra ibi 
mo kórìíra ìgbéraga àti agídí, 
ìwà ibi àti ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn. 
 14 Ìmọ̀ràn àti ọgbọ́n tí ó yè kooro jẹ́ tèmi 
mo ní òye àti agbára. 
 15 Nípasẹ̀ mi ni ọba ń ṣàkóso 
tí àwọn aláṣẹ sì ń ṣe òfin tí ó dára. 
 16 Nípasẹ̀ mi àwọn ọmọ-aládé ń ṣàkóso, 
àti gbogbo ọlọ́lá tí ń ṣàkóso ilẹ̀ ayé. 
 17 Mo fẹ́ràn àwọn tí ó fẹ́ràn mi, 
àwọn tí ó sì wá mi rí mi. 
 18 Lọ́dọ̀ mi ni ọrọ̀ àti ọlá wà, 
ọrọ̀ tí í tọ́jọ́ àti ìgbéga rere. 
 19 Èso mi dára ju wúrà dáradára lọ; 
ohun tí mò ń mú wá ju àṣàyàn fàdákà lọ. 
 20 Mò ń rìn ní ọ̀nà òdodo, 
ní ojú ọ̀nà òtítọ́, 
 21 mò ń fi ọrọ̀ fún gbogbo àwọn tí ó fẹ́ràn mi 
mo sì ń mú kí ilé ìṣúra wọn kún. 
 22 “Èmi ni Olúwa kọ́kọ́ dá nínú iṣẹ́ rẹ̀. 
Ṣáájú àwọn iṣẹ́ rẹ̀ àtijọ́; 
 23 a ti yàn mí láti ayérayé, 
láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, kí ayé tó bẹ̀rẹ̀. 
 24 Nígbà tí kò tí ì sí Òkun, ni a ti bí mi, 
nígbà tí kò tí ì sí ìsun tí ó ní omi nínú; 
 25 kí a tó fi àwọn òkè sí ipò wọn, 
ṣáájú àwọn òkè ni a ti bí mi, 
 26 kí ó tó dá ilẹ̀ ayé tàbí àwọn oko rẹ̀ 
tàbí èyíkéyìí nínú eruku ayé. 
 27 Mo wà níbẹ̀ nígbà tí ó fi àwọn ọ̀run sí ipò wọn, 
nígbà tí ó fi òsùwọ̀n àyíká sórí ibú omi, 
 28 nígbà tí ó ṣẹ̀dá òfúrufú lókè 
tí ó sì fi orísun ibú omi sí ipò rẹ̀ láì le è yẹsẹ̀, 
 29 nígbà tí ó ṣe ààlà fún omi Òkun 
kí omi má ba à kọjá ààlà àṣẹ rẹ̀, 
àti nígbà tí ó pààlà ìpìlẹ̀ ayé. 
 30 Nígbà náà èmi ni gbẹ́nàgbẹ́nà ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ 
mo kún fún inú dídùn lójoojúmọ́, 
mo ń yọ̀ nígbà gbogbo níwájú rẹ̀. 
 31 Mo ń yọ̀ nínú gbogbo àgbáyé tí ó dá 
mo sì ní inú dídùn sí àwọn ọmọ ènìyàn. 
 32 “Nítorí náà báyìí, ẹ̀yin ọmọ mi, 
ìbùkún ni fún àwọn tí ó pa ọ̀nà mi mọ́. 
 33 Fetí sí ìtọ́sọ́nà mi kí o sì gbọ́n; 
má ṣe pa á tì sápá kan. 
 34 Ìbùkún ni fún ẹni tí ó fetísílẹ̀ sí mi, 
tí ń ṣọ́nà ní ẹnu-ọ̀nà mi lójoojúmọ́, 
tí ń dúró ní ẹnu-ọ̀nà mi. 
 35 Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá rí mi rí ìyè 
ó sì rí ojúrere gbà lọ́dọ̀ Olúwa. 
 36 Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ láti rí ń pa ara rẹ̀ lára 
gbogbo ẹni tí ó kórìíra mi fẹ́ ikú.”