38
Ọlọ́run pe Jobu níjà
1 Nígbà náà ní Olúwa dá Jobu lóhùn láti inú ìjì àjàyíká wá, ó sì wí pé,
2 “Ta ni èyí tí ń fi ọ̀rọ̀ àìlóye
láti fi ṣókùnkùn bo ìmọ̀ mi?
3 Di ẹ̀gbẹ́ ara rẹ ní àmùrè bí ọkùnrin nísinsin yìí,
nítorí pé èmi yóò béèrè lọ́wọ́ rẹ
kí o sì dá mi lóhùn.
4 “Níbo ni ìwọ wà nígbà tí mo fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀?
Wí bí ìwọ bá mòye.
5 Ta ni ó fi ìwọ̀n rẹ lélẹ̀, dájú bí ìwọ bá mọ̀ ọ́n?
Tàbí ta ni ó ta okùn wíwọ̀n sórí rẹ?
6 Lórí ibo ni a gbé kan ìpìlẹ̀ rẹ̀ mọ́,
tàbí ta ni ó fi òkúta igun rẹ̀ lélẹ̀,
7 nígbà náà àwọn ìràwọ̀ òwúrọ̀ jùmọ̀ kọrin pọ̀,
tí gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run hó ìhó ayọ̀?
8 “Tàbí ta ni ó fi ìlẹ̀kùn sé omi òkun mọ́,
nígbà tí ó ya padà bí ẹni pé ó ti inú jáde wá.
9 Nígbà tí mo fi àwọsánmọ̀ ṣe aṣọ rẹ̀,
tí mo sì fi òkùnkùn biribiri ṣe ọ̀já ìgbà inú rẹ̀.
10 Nígbà tí mo ti pàṣẹ ìpinnu mi fún un,
tí mo sì ṣe bèbè àti ìlẹ̀kùn.
11 Tí mo sì wí pé níhìn-ín ni ìwọ ó dé, kí o má sì rékọjá,
níhìn-ín sì ni ìgbéraga rẹ yóò gbé dúró mọ?
12 “Ìwọ pàṣẹ fún òwúrọ̀ láti ìgbà ọjọ́ rẹ̀ wá,
ìwọ sì mú ìlà-oòrùn mọ ipò rẹ̀,
13 í ó lè di òpin ilẹ̀ ayé mú,
ki a lè gbọ́n àwọn ènìyàn búburú kúrò nínú rẹ̀?
14 Kí ó yí padà bí amọ̀ fún èdìdì amọ̀,
kí gbogbo rẹ̀ kí ó sì fi ara rẹ̀ hàn bí ẹni pé nínú aṣọ ìgúnwà.
15 A sì fa ìmọ́lẹ̀ wọn sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ ènìyàn búburú,
apá gíga ni a sì ṣẹ́.
16 “Ìwọ ha wọ inú ìsun òkun lọ rí bí?
Ìwọ sì rìn lórí ìsàlẹ̀ ibú ńlá?
17 A ha ṣílẹ̀kùn ikú sílẹ̀ fún ọ rí bí,
ìwọ sì rí ìlẹ̀kùn òjìji òkú?
18 Ìwọ mòye ìbú ayé bí?
Sọ bí ìwọ bá mọ gbogbo èyí.
19 “Ọ̀nà wo ni ìmọ́lẹ̀ ń gbé?
Bí ó ṣe ti òkùnkùn, níbo ni ipò rẹ̀,
20 tí ìwọ í fi mú un lọ sí ibi àlá rẹ̀,
tí ìwọ ó sì le mọ ipa ọ̀nà lọ sínú ilé rẹ̀?
21 Ìwọ mọ èyí, nítorí nígbà náà ni a bí ọ?
Iye ọjọ́ rẹ sì pọ̀.
22 “Ìwọ ha wọ inú ìṣúra ìdì òjò lọ rí bí,
ìwọ sì rí ilé ìṣúra yìnyín rí,
23 tí mo ti fi pamọ́ de ìgbà ìyọnu,
dé ọjọ́ ogun àti ìjà?
24 Ọ̀nà wo ni ó lọ sí ibi tí ìmọ́lẹ̀ fi ń la,
tí afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn ń tàn káàkiri lórí ilẹ̀ ayé?
25 Ta ni ó la ipadò fún ẹ̀kún omi,
àti ọ̀nà fún mọ̀nàmọ́ná àrá,
26 láti mú u rọ̀jò sórí ayé níbi tí ènìyàn kò sí,
ní aginjù níbi tí ènìyàn kò sí;
27 láti mú ilẹ̀ tútù, ijù àti aláìro
láti mú àṣẹ̀ṣẹ̀yọ ewéko rú jáde?
28 Òjò ha ní baba bí?
Tàbí ta ni o bí ìkún ìṣe ìrì?
29 Láti inú ta ni ìdì omi ti jáde wá?
Ta ni ó bí ìrì dídì ọ̀run?
30 Nígbà tí omi di líle bí òkúta,
nígbà tí ojú ibú ńlá sì dìpọ̀.
31 “Ìwọ ha le fi ọ̀já de àwọn ìràwọ̀ Pleiadesi dáradára?
Tàbí ìwọ le tún di ìràwọ̀ Orioni?
32 Ìwọ le mú àwọn àmì méjìlá ìràwọ̀ Masaroti jáde wá nígbà àkókò wọn?
Tàbí ìwọ le ṣe amọ̀nà Beari pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀?
33 Ǹjẹ́ ìwọ mọ ìlànà ọ̀run?
Ìwọ le fi ìjọba Ọlọ́run lélẹ̀ lórí ayé?
34 “Ìwọ le gbé ohùn rẹ sókè dé àwọsánmọ̀
kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi kí ó lè bò ọ́?
35 Ìwọ le rán mọ̀nàmọ́ná kí wọn kí ó le lọ,
ní ọ̀nà wọn kí wọn kí ó sì wí fún wọn pé, ‘Àwa nìyí’?
36 Ta ni ó fi ọgbọ́n pamọ́ sí odò ikùn
tàbí tí ó fi òye sínú àyà?
37 Ta ni ó fi ọgbọ́n ka iye àwọsánmọ̀?
Ta ni ó sì mú ìgò ọ̀run dà jáde,
38 nígbà tí erùpẹ̀ di líle,
àti ògúlùtu dìpọ̀?
39 “Ìwọ ha dẹ ọdẹ fún abo kìnnìún bí?
Ìwọ ó sì tẹ ebi ẹgbọrọ kìnnìún lọ́rùn,
40 nígbà tí wọ́n bá mọ́lẹ̀ nínú ihò
tí wọ́n sì ba ní ibùba de ohun ọdẹ?
41 Ta ni ó ń pèsè ohun jíjẹ fún ẹyẹ ìwò,
nígbà tí àwọn ọmọ rẹ ń ké pe Ọlọ́run,
tí wọ́n sì máa ń fò kiri nítorí àìní ohun jíjẹ?