28
Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n àti òye Jobu
Nítòótọ́, koto fàdákà ń bẹ,
àti ibi tí wọ́n ti máa ń da wúrà.
Nínú ilẹ̀ ni à ń gbé ń wa irin,
bàbà ni a sì ń dà láti inú òkúta wá.
Ènìyàn ni ó fi òpin si òkùnkùn,
ó sì ṣe àwárí ìṣúra
láti inú òjìji ikú sí ìhà gbogbo.
Wọ́n wa ihò ilẹ̀ tí ó jì sí àwọn tí ń gbé òkè,
àwọn tí ẹsẹ̀ ènìyàn gbàgbé wọ́n rọ́ sí ìsàlẹ̀,
wọ́n rọ́ sí ìsàlẹ̀ jìnnà sí àwọn ènìyàn.
Bí ó ṣe ti ilẹ̀ ni, nínú rẹ̀ ni oúnjẹ ti ń jáde wá,
àti ohun tí ó wà ní ìsàlẹ̀ ni ó yí padà bi iná;
òkúta ibẹ̀ ni ibi òkúta safire,
o sì ní erùpẹ̀ wúrà.
Ipa ọ̀nà náà ni ẹyẹ kò mọ̀,
àti ojú gúnnugún kò rí i rí.
Àwọn ẹranko agbéraga kò rìn ibẹ̀ rí,
bẹ́ẹ̀ ni kìnnìún tí ń ké ramúramù kò kọjá níbẹ̀ rí.
Ó fi ọwọ́ rẹ̀ lé akọ òkúta,
ó yí òkè ńlá po láti ìdí rẹ̀ wá.
10 Ó sì la ipa odò ṣíṣàn nínú àpáta,
ojú inú rẹ̀ sì rí ohun iyebíye gbogbo.
11 Ó sì ṣe ìṣàn odò kí ó má ṣe kún àkúnya,
ó sì mú ohun tí ó pamọ́ hàn jáde wá sí ìmọ́lẹ̀.
 
12 Ṣùgbọ́n níbo ni á ó gbé wá ọgbọ́n rí,
níbo sì ni òye ń gbe?
13 Ènìyàn kò mọ iye rẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni a kò le è rí i ní ilẹ̀ àwọn alààyè.
14 Ọ̀gbun wí pé, “Kò sí nínú mi”;
omi òkun sì wí pé, “Kò si nínú mi.”
15 A kò le è fi wúrà rà á,
bẹ́ẹ̀ ni a kò le è fi òsùwọ̀n wọn fàdákà ní iye rẹ̀.
16 A kò le è fi wúrà Ofiri, tàbí òkúta óníkìsì iyebíye,
tàbí òkúta safire díye lé e.
17 Wúrà àti òkúta kristali kò tó ẹgbẹ́ rẹ̀;
bẹ́ẹ̀ ni a kò le è fi ohun èlò wúrà ṣe pàṣípàrọ̀ rẹ̀.
18 A kò lè dárúkọ iyùn tàbí òkúta jasperi;
iye ọgbọ́n sì ju iyùn lọ.
19 Òkúta topasi ti Kuṣi kò tó ẹgbẹ́ rẹ̀;
bẹ́ẹ̀ ni a kò le fi wúrà dáradára díwọ̀n iye rẹ̀.
 
20 Níbo ha ni ọgbọ́n ti jáde wá?
Tàbí níbo ni òye ń gbé?
21 A rí i pé, ó fi ara sinko kúrò ní ojú àwọn alààyè gbogbo,
ó sì fi ara sin fún ẹyẹ ojú ọ̀run.
22 Ibi ìparun àti ikú wí pé,
àwa ti fi etí wa gbúròó rẹ̀.
23 Ọlọ́run ni ó mọ òye ipa ọ̀nà rẹ̀,
òun ni ó sì mọ ibi tí ó ń gbé.
24 Nítorí pé ó wòye dé òpin ayé,
ó sì rí gbogbo ìsàlẹ̀ ọ̀run,
25 láti dà òsùwọ̀n fún afẹ́fẹ́,
ó sì fi òsùwọ̀n wọ́n omi.
26 Nígbà tí ó pàṣẹ fún òjò,
tí ó sì la ọ̀nà fún mọ̀nàmọ́ná àrá,
27 nígbà náà ni ó rí i, ó sì sọ ọ́ jáde;
ó pèsè rẹ̀ sílẹ̀, ó sì ṣe ìwádìí rẹ̀ rí.
28 Àti fún ènìyàn ni ó wí pé,
“Kíyèsi i, ẹ̀rù Olúwa èyí ni ọgbọ́n,
àti láti jáde kúrò nínú ìwà búburú èyí ni òye.”