24
Ìbéèrè Jobu
1 “Ṣe bí ìgbà kò pamọ́ lọ́dọ̀ Olódùmarè fún ìdájọ́?
Èéṣe tí ojúlùmọ̀ rẹ̀ kò fi rí ọjọ́ rẹ̀?
2 Wọ́n a sún àmì ààlà ilẹ̀,
wọ́n á fi agbára kó agbo ẹran lọ, wọ́n a sì bọ́ wọn.
3 Wọ́n á sì da kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ aláìní baba lọ,
wọ́n a sì gba ọ̀dá màlúù opó ní ohun ògo.
4 Wọ́n á bi aláìní kúrò lójú ọ̀nà,
àwọn tálákà ayé a fi agbára sá pamọ́.
5 Kíyèsi i, bí i kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó nínú ijù ni àwọn tálákà jáde lọ sí iṣẹ́ wọn,
wọ́n a tètè dìde láti wá ohun ọdẹ;
ijù pèsè oúnjẹ fún wọn àti fún àwọn ọmọ wọn.
6 Olúkúlùkù a sì sá ọkà oúnjẹ ẹran rẹ̀ nínú oko,
wọn a sì ká ọgbà àjàrà ènìyàn búburú.
7 Ní ìhòhò ni wọn máa sùn láìní aṣọ,
tí wọn kò ní ìbora nínú òtútù.
8 Ọ̀wààrà òjò òkè ńlá sì pa wọ́n,
wọ́n sì lẹ̀ mọ́ àpáta nítorí tí kò sí ààbò.
9 Wọ́n já ọmọ aláìní baba kúrò ní ẹnu ọmú,
wọ́n sì gbà ọmọ tálákà nítorí gbèsè.
10 Wọ́n rìn kiri ní ìhòhò láìní aṣọ;
àwọn tí ebi ń pa rẹrù ìdì ọkà.
11 Àwọn ẹni tí ń fún òróró nínú àgbàlá wọn,
tí wọ́n sì ń tẹ ìfúntí àjàrà, síbẹ̀ òǹgbẹ sì ń gbẹ wọn.
12 Àwọn ènìyàn ń kérora láti ìlú wá,
ọkàn àwọn ẹni tí ó gbọgbẹ́ kígbe sókè fún ìrànlọ́wọ́
síbẹ̀ Ọlọ́run kò kíyèsi àṣìṣe náà.
13 “Àwọn ni ó wà nínú àwọn tí ó ṣọ̀tẹ̀ sí ìmọ́lẹ̀,
wọn kò mọ̀ ipa ọ̀nà rẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni wọn kò dúró nípa ọ̀nà rẹ̀.
14 Apànìyàn a dìde ní àfẹ̀mọ́júmọ́,
a sì pa tálákà àti aláìní,
àti ní òru a di olè.
15 Ojú alágbèrè pẹ̀lú dúró kí ilẹ̀ ṣú díẹ̀;
‘Ó ní, ojú ẹnìkan kì yóò rí mi,’
ó sì fi ìbòjú bojú rẹ̀.
16 Ní òkùnkùn wọn á rúnlẹ̀ wọlé,
tí wọ́n ti fi ojú sọ fún ara wọn ní ọ̀sán,
wọn kò mọ̀ ìmọ́lẹ̀.
17 Nítorí pé bí òru dúdú ní òwúrọ̀ fún gbogbo wọn;
nítorí tí wọn sì mọ̀ ìbẹ̀rù òkùnkùn.
18 “Ó yára lọ bí ẹni lójú omi;
ìpín wọn ní ilé ayé ni a ó parun;
òun kò rìn lọ mọ́ ní ọ̀nà ọgbà àjàrà.
19 Gẹ́gẹ́ bi ọ̀dá àti òru ní í mú omi òjò-dídì yọ́,
bẹ́ẹ̀ ní isà òkú í run àwọn tó dẹ́ṣẹ̀.
20 Inú ìbímọ yóò gbàgbé rẹ̀,
kòkòrò ní yóò máa fi adùn jẹun lára rẹ̀;
a kì yóò rántí ènìyàn búburú mọ́;
bẹ́ẹ̀ ní a ó sì ṣẹ ìwà búburú bí ẹní ṣẹ́ igi.
21 Ẹni tí o hù ìwà búburú sí àgàn
tí kò ṣe rere sí opó.
22 Ọlọ́run fi ipá agbára rẹ̀ fa alágbára,
bí wọ́n tilẹ̀ fìdímúlẹ̀, kò sí ìrètí ìyè fún wọn.
23 Ọlọ́run sì fi àìléwu fún un,
àti nínú èyí ni a ó sì tì i lẹ́yìn,
ojú rẹ̀ sì wà ní ipa ọ̀nà wọn.
24 A gbé wọn lékè nígbà díẹ̀, wọ́n kọjá lọ;
a sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀, a sì mú wọn kúrò ní ọ̀nà bí àwọn ẹlòmíràn,
a sì ké wọn kúrò bí orí síírí ọkà bàbà.
25 “Ǹjẹ́, bí kò bá rí bẹ́ẹ̀ nísinsin yìí, ta ni yóò mú mi ní èké,
tí yóò sì sọ ọ̀rọ̀ mi di aláìníláárí?”