11
Sofari fi ẹ̀sùn irọ́ pípa àti àìṣòótọ́ kan Jobu
1 Ìgbà náà ni Sofari, ará Naama, dáhùn, ó sì wí pé,
2 “A ha lè ṣe kí a máa dáhùn sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rọ̀?
A ha lè fi gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí da ènìyàn láre?
3 Ṣé àmọ̀tán rẹ le mú ènìyàn pa ẹnu wọn mọ́ bí?
Ṣé ẹnikẹ́ni kò ní bá ọ wí bí ìwọ bá yọ ṣùtì sí ni?
4 Ìwọ sá à ti wí fún Ọlọ́run pé, ‘Ìṣe mi jẹ́ aláìléérí,
èmi sì mọ́ ní ojú rẹ.’
5 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ìbá jẹ́ sọ̀rọ̀,
kí ó sì ya ẹnu rẹ̀ sí ọ
6 kí ó sì fi àṣírí ọgbọ́n hàn ọ́ pé, ó pọ̀ ju òye ènìyàn lọ,
nítorí náà, mọ̀ pé Ọlọ́run ti
gbàgbé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kan.
7 “Ìwọ ha le ṣe àwárí ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run bí?
Ìwọ ha le ṣe àwárí ibi tí Olódùmarè dé bi?
8 Ó ga ju àwọn ọ̀run lọ; kí ni ìwọ le è ṣe?
Ó jìn ju jíjìn isà òkú lọ; kí ni ìwọ le mọ̀?
9 Ìwọ̀n rẹ̀ gùn ju ayé lọ,
ó sì ní ibú ju òkun lọ.
10 “Bí òun bá rékọjá, tí ó sì sé ọnà
tàbí tí ó sì mú ni wá sí ìdájọ́, ǹjẹ́, ta ni ó lè dí i lọ́wọ́?
11 Òun sá à mọ ẹlẹ́tàn ènìyàn;
àti pé ṣé bí òun bá rí ohun búburú, ṣé òun kì i fi iyè sí i?
12 Ṣùgbọ́n òmùgọ̀ ènìyàn ki yóò di ọlọ́gbọ́n
bi ko ti rọrùn fún ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó láti bí ènìyàn.
13 “Bí ìwọ bá fi ọkàn rẹ fún un,
tí ìwọ sì na ọwọ́ rẹ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀,
14 bí ìwọ bá gbé ẹ̀ṣẹ̀ tí ń bẹ ní ọwọ́ rẹ jù sọnù
tí ìwọ kò sì jẹ́ kí aburú gbé nínú àgọ́ rẹ,
15 nígbà náà ni ìwọ ó gbé ojú rẹ sókè láìní àbàwọ́n,
àní ìwọ yóò dúró ṣinṣin, ìwọ kì yóò sì bẹ̀rù.
16 Nítorí pé ìwọ ó gbàgbé ìṣòro rẹ;
ìwọ ó sì rántí rẹ̀ bí omi tí ó ti sàn kọjá lọ.
17 Ọjọ́ ayé rẹ yóò sì mọ́lẹ̀ ju ọ̀sán gangan lọ,
bí òkùnkùn tilẹ̀ bò ọ́ mọ́lẹ̀ nísinsin yìí, ìwọ ó dàbí òwúrọ̀.
18 Ìwọ ó sì wà láìléwu, nítorí pé ìrètí wà;
àní ìwọ ó rin ilé rẹ wò, ìwọ ó sì sinmi ní àlàáfíà.
19 Ìwọ ó sì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú, kì yóò sì sí ẹni tí yóò dẹ́rùbà ọ́,
àní ènìyàn yóò máa wá ojúrere rẹ.
20 Ṣùgbọ́n ojú ìkà ènìyàn yóò mófo;
gbogbo ọ̀nà àbáyọ ni yóò nù wọ́n,
ìrètí wọn a sì dàbí ẹni tí ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́.”