Ìwé Esra
1
Kirusi ran àwọn tí a kó nígbèkùn lọ́wọ́ láti padà
Es 5.13; 6.3; 2Ki 36.22,23.Ní ọdún kìn-ín-ní Kirusi, ọba Persia, kí a lè mú ọ̀rọ̀ Olúwa tí Jeremiah sọ ṣẹ, Olúwa ru ọkàn Kirusi ọba Persia sókè láti ṣe ìkéde jákèjádò gbogbo agbègbè ìjọba rẹ̀, kí ó sì ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ pé,
“Èyí ni ohun tí Kirusi ọba Persia wí pé:
“ ‘Olúwa, Ọlọ́run ọ̀run, ti fún mi ní gbogbo ìjọba ayé. Ó sì ti yàn mí láti kọ́ tẹmpili Olúwa fún un ní Jerusalẹmu tí ó wà ní Juda. Ẹnikẹ́ni nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ láàrín yín—kí Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀, kí ó sì gòkè lọ sí Jerusalẹmu tí ó wà ní Juda, láti kọ́ tẹmpili Olúwa Ọlọ́run Israẹli, Ọlọ́run tí ó wà ní Jerusalẹmu. Kí àwọn ènìyàn ní ibikíbi tí ẹni náà bá ń gbé kí ó fi fàdákà àti wúrà pẹ̀lú ohun tí ó dára àti ẹran ọ̀sìn, pẹ̀lú ọrẹ àtinúwá ràn án lọ́wọ́ fún tẹmpili Ọlọ́run ní Jerusalẹmu.’ ”
Nígbà náà àwọn olórí ìdílé Juda àti Benjamini àti àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi—olúkúlùkù ẹni tí Ọlọ́run ti fọwọ́ tọ́ ọkàn rẹ̀—múra láti gòkè lọ láti kọ ilé Olúwa ní Jerusalẹmu. Gbogbo àwọn aládùúgbò wọn ràn wọ́n lọ́wọ́ pẹ̀lú ohun èlò ti fàdákà àti wúrà, pẹ̀lú onírúurú ohun ìní àti ẹran ọ̀sìn àti pẹ̀lú àwọn ẹ̀bùn iyebíye, ní àfikún si gbogbo àwọn ọrẹ àtinúwá.
Ní àfikún, ọba Kirusi mú àwọn ohun èlò tí ó jẹ́ ti ilé Olúwa jáde wá, tí Nebukadnessari ti kó lọ láti Jerusalẹmu tí ó sì ti kó sí ilé òrìṣà rẹ̀. Kirusi ọba Persia pàṣẹ fún Mitredati olùṣọ́ ilé ìṣúra láti kó wọn jáde, ó sì kà wọ́n fún Ṣeṣbassari ìjòyè Juda.
 
Èyí ni iye wọn.
 
Ọgbọ̀n àwo wúrà 30
Ẹgbẹ̀rún àwo fàdákà 1,000
Àwo ìrúbọ fàdákà mọ́kàndínlọ́gbọ̀n 29
10 Ọgbọ̀n àdému wúrà 30
Irinwó ó lé mẹ́wàá oríṣìí àdému fàdákà mìíràn 410
Ẹgbẹ̀rún kan àwọn ohun èlò mìíràn 1,000
 
11 Gbogbo ohun èlò wúrà àti ti fàdákà ní àpapọ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún ó lé irinwó (5,400).
 
Ṣeṣbassari kó gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí wá pẹ̀lú àwọn ìgbèkùn tí ó gòkè wá láti Babeli sí Jerusalẹmu.

1:1 Es 5.13; 6.3; 2Ki 36.22,23.